Mark 5:21-43

Òkú ọmọbìnrin kan àti obìnrin aláìsàn

21 aNígbà tí Jesu sì ti inú ọkọ̀ rékọjá sí apá kejì Òkun, ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn péjọ yí i ká ní etí Òkun. 22 bỌ̀kan nínú àwọn olórí Sinagọgu tí à ń pè ni Jairu wá sọ́dọ̀ Jesu, nígbà tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀. 23 cÓ sì bẹ̀ ẹ́ gidigidi pé, “Ọmọbìnrin mi wà lójú ikú, mo bẹ̀ ọ́, wá fi ọwọ́ rẹ lé e, kí ara rẹ̀ lè dá, kí ó sì yè.” 24Jesu sì ń bá a lọ.

Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn.
25Obìnrin kan sì wà láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, tí ó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún odidi ọdún méjìlá. 26Ẹni tí ojú rẹ̀ sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn oníṣègùn, tí ó sì ti ná gbogbo ohun tí ó ní, síbẹ̀ kàkà kí ó san, ó ń burú sí i. 27Nígbà tí ó sì gbúròó iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe, ìdí nìyìí tí ó fi wá sẹ́yìn rẹ̀, láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀. 28Nítorí ti ó rò ní ọkàn rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá à lè fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.” 29Ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì gbẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun sì mọ̀ lára rẹ̀ pé, a mú òun láradá kúrò nínú ààrùn náà.

30 dLọ́gán, Jesu sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé agbára jáde lára òun. Ó yípadà láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì béèrè, “Ta ni ó fi ọwọ́ kan aṣọ mi?”

31Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó rọ̀gbà yí ọ ká, ìwọ sì tún ń béèrè ẹni tí ó fi ọwọ́ kàn ọ́?”

32Síbẹ̀, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí wò yíká láti rí ẹni náà, tí ó fi ọwọ́ kan òun. 33Nígbà náà, obìnrin náà kún fún ìbẹ̀rù àti ìwárìrì nítorí ó ti mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lára òun. Ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ gbogbo òtítọ́ fún un. 34 eJesu sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá: Máa lọ ní àlàáfíà, ìwọ sì ti sàn nínú ààrùn rẹ.”

35Bí Jesu sì ti ń ba obìnrin náà sọ̀rọ̀, àwọn ìránṣẹ́ dé láti ilé Jairu olórí Sinagọgu wá, wọ́n wí fún un pé, ọmọbìnrin rẹ ti kú, àti pé kí wọn má ṣe yọ Jesu lẹ́nu láti wá, nítorí ó ti pẹ́ jù.

36Ṣùgbọ́n bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún Jairu pé, “Má bẹ̀rù, sá à gbàgbọ́ nìkan.”

37 fNígbà náà, Jesu dá ọ̀pọ̀ ènìyàn náà dúró. Kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun lẹ́yìn lọ ilé Jairu, bí kò ṣe Peteru, Jakọbu àti Johanu arákùnrin Jakọbu. 38Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, Jesu rí i pé gbogbo nǹkan ti dàrú. Ilé kún fún àwọn tí ń sọkún, àti àwọn tí ń pohùnréré ẹkún. 39Ó wọ inú ilé lọ, o sì bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń sọkún tí ẹ sì ń pohùnréré ẹkún? Ọmọbìnrin náà kò kú, ó sùn lásán ni.” 40Wọ́n sì fi í rẹ́rìn-ín.

Ṣùgbọ́n ó sọ fún gbogbo wọn láti bọ́ síta, ó mú baba àti ìyá ọmọ náà, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́ta. Ó sì wọ inú yàrá tí ọmọbìnrin náà gbé dùbúlẹ̀ sí.
41 gÓ gbá a ní ọwọ́ mú, ó sì wí pé, “Talita kuumi” (tí ó túmọ̀ sí, ọmọdébìnrin, dìde dúró). 42Lẹ́sẹ̀kan náà, ọmọbìnrin náà sì dìde. Ó sì ń rìn, ẹ̀rù sì bà wọ́n, ẹnu sì ya àwọn òbí rẹ̀ gidigidi. 43 hJesu sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọn má ṣe sọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ó sì wí fún wọn kí wọn fún ọmọbìnrin náà ní oúnjẹ.

Copyright information for YorBMYO